AKAYE N TESIWAJU: Orisi ero ni o n wa si opolo mi,se lati igba ti - TopicsExpress



          

AKAYE N TESIWAJU: Orisi ero ni o n wa si opolo mi,se lati igba ti mo ti wa ninu igbo yii,mio ri eran gidi pa,afi bii etu,bii oya.ojo kan tie wa ti mio ri eran kankan pa.bayii ni mo ri isa okete kan ti o dan gbin bii ona.o daju wipe okete naa gbodo wa nile. Mo mu ada,mo n de isa okete,bi mo se n gbe isa yii beeni ona re n jin sii,eemo nla.mio kan ese ona re saa n jin sii ni.mo waa ro aduru wahala ti mo tise seyin,asiko yii gan ni mo ranti owe yoruba to wipe,eni ti n de isa okete,oluwa n de idi ohun naa pelu.kii se ebi emi naa,ebi ti de oju re ni,beeni ko si agbokanle miran ninu igbo.mo mura si ile gbigbe ki n baa lee pa isinmi po lori itan okete.oto ni ohun a ro,oto ni ohun ti a ba,isa okete ni mo n gbe,akeeke ni o yo ninu isa,eru bami tori mio ri iru akeeke bee ri.otobi to adie awonsi.bi mo se ti owo bo isa naa bayii,eyin okete ni mo pee,mo yo owo mi pelu agidi,igba yii gan ni mo too mo pe oran ni nbe ninu isa ti mo n gbe.bi o se boota bayii,mo ta idi meyin,ni mo ba gbe ada lee ni aarin ori re.emo je ki n tan yii,ebi ni mo basun ni ale ojo yii. Gbogbo awon ero wonyii ni mo ro papo ti mo si woo pe iru ebi ti o pami ni ojo yii ko gbodo tun pami mo.ni igba ti mo ri agbonrin kan,mo da ebora yii duro,mo ni mo fee to.abii e ko wa ri agbonrin naa,ko tie tun saa fun mi,o tubo n jeun lo ni,arifin ile iyagbe,iku ni o fi n sere yii,mo wo atari re sunsun,mo ju bajinatu haa ni agbari,ina dun.eru olorun bami,torii eran naa o subu,ko tie se bii igba wipe ibon ba ni atari,bee emi ti mo yin ibon mo pe,eekan ni iro mi ibon mi maa n mu eran bi o ti lee wu kio buru to. Ebora naa ko soro,o gbemi si ejika pada,irin ajo tun tesiwaju. Emi ree,ebi n pami,beeni mio mo ibi ti a n lo.ero kan wa simi lopolo.ti o ba tie je pe ebora yii fee loo fimi sesin nko? Nibo gan ni a nlo? Kini a fee loo se gan? See eekan ni omokurin ku,bio ti mo ni yio mo,oko iyawo yio se ilodi.leyin irin bii wakati mefa,a kan apata nla kan ti o da bii oke olumo,amo ko tobi too,sugbon giga re too daadaa.eru bami nitori oniruuru eda ti a ba nibe,ebora yii gbemi sile,emi naa n tele bi a ti nlo,ilekun rogodo kan wa ni ibi ti awon ebora posi yii,bawo ni ase fee wole gan? Eni ti o ga,bawo ni yio se wole? Oju ona ohun gan ko lee gba emi gan dipo eni ti mo da bii esinsin loju re? Iwe "IJA ALAGBARA" ni a n ka lowo,o di ale kia too tesiwaju pelu ase oluwa.emoo fi okan bawa bo, ekuu ikale leekan sii
Posted on: Fri, 27 Sep 2013 08:12:27 +0000

Trending Topics



Recently Viewed Topics




© 2015