E tun wa gbo! Oluko kan n salaye oja tita, marketing fun akekoo re - TopicsExpress



          

E tun wa gbo! Oluko kan n salaye oja tita, marketing fun akekoo re kan: 1. O ri omobinrin kan to mura daadaa ni pati. O lo baa, o so pe: “Olowo ni mi. Fe mi!” - Iyen ni won n pe ni oja tita taara, Direct Marketing. 2. O wa ni pati pelu awon ore re, o si ri obinrin kan to wu o. Okan ninu awon ore re lo baa, o nawo si o. O ni: “Olowo ni. Fee!” – Iyen ni ipolowo oja, Advertising. 3. O wa ni pati, o si ri obinrin kan to fain. Omobinrin naa wa ba o, o ni: “Olowo ni o! Se mo le fe o?” - Iyen ni ka da oja mo, Brand Recognition. 4. O wa ni pati, o si ri obinrin kan to dara. O lo baa, o ni: “Olowo ni mi. Se o le fe mi?” Omobinrin naa wo o tika-tegbin, o si gbe igbati fun o. - Iyen ni, erongba onibaara, Customer Feedback. 5. O wa ni pati, o si ri obinrin kan to rewa. O lo baa, o ni: “Olowo ni mi. Fe mi!” Lo ba fi iwo ati oko re mo ara yin.- Iyen ni alafo to wa laarin kara-kata, Demand and Supply Gap 6. O wa ni pati, o si ri obinrin kan to rewa. O lo baa, o ni: “Mo lowo lowo, Fe mi!”, Bee ni iyawo re yo lookan. – Iyen ni won n pe, ki won o ma faaye gbani lati wo oja tuntun, Restriction for Entering New Markets. A ku ise oni o. Se owo ya? Oorun ire la o sun o.
Posted on: Mon, 12 Aug 2013 21:00:31 +0000

Trending Topics



Recently Viewed Topics




© 2015