ẸRIN KAN! . . Arakunrin kan rẹrin musẹ kan si ajeji kan ti - TopicsExpress



          

ẸRIN KAN! . . Arakunrin kan rẹrin musẹ kan si ajeji kan ti inu rẹ ko dun. Ẹrin kan naa jẹ ki ara ajeji kan naa ya. O ranti awọn oore atijọ ti ọrẹ rẹ kan ṣe fun-un, o si kọ lẹta idupẹ kan sii. Inu ọrẹ yii dun to bẹẹ gẹ fun lẹta idupẹ yii ti o fi fi owo gọbọyi t’ọrẹ fun agbe-ounjẹ(atte ndant) kan lẹyin ti o jẹun tan. Ẹnu ya agbe-ounjẹ kan fun owo gọbọyi yii, ti o fi fi gbogbo rẹ ta tẹtẹ. Ni ọjọ keji, o gba owo bibori tẹtẹ ti o ta, o si fun ọkunrin kan l’oju popo lara rẹ. okunrin oju popo naa dupẹ; o si jẹun fun ọsẹ kan ti ko ti fi ri nkankan jẹ. Lẹyin ti o jẹun tan, o lọ si ile-kereje rẹ, ko si mọ ni igba naa ewu ti ohun yoo koju. Ni ọna, o gbe ọmọ-aja kan ti otutu nmu ki o baa le ya ooru ni ile rẹ. Inu aja kan naa dun lati kuro ninu iji. Ni alẹ ọjọ naa, ile gba ina. Ọmọ aja naa gbo bii aago itaniji(alarm) o gbo titi o fi ji gbogbo ara ile, o si gba wọn lọwọ ewu. Ọkan lara awọn ọmọde-kunrin ti a gbala dagba, o si di Olori orile-ede. Ohun to fa gbogbo eleyi nipe nitori wipe ẹnikan rẹrin musẹ ti ko kasi kan ti ko si naa ni owo kankan. Nitori naa, ẹrin n ṣewosan o si nṣiṣẹ aramanda tẹnikan o lero. Ẹjẹ kia rẹrin sirawa bayii. Ẹrin temi ree: ẸRIN KEKEKEKEKEKEKEK EKEKEKEKEKEKEKEKEKEKEKEKEKEKEK EKEKEKEKEKEKEKEKE.
Posted on: Thu, 15 Aug 2013 15:52:01 +0000

Trending Topics



Recently Viewed Topics




© 2015