ỌLỌRUN duro ninu ijọ awọn alagbara: o nṣe idajo ninu - TopicsExpress



          

ỌLỌRUN duro ninu ijọ awọn alagbara: o nṣe idajo ninu awọn ọlọrun. Ẹyin o ti ṣe idajo aiṣootọ pẹ to, ti ẹ o si ma ṣe ojusaaju awon eniyan buburu? Ṣe idajo talaka, ati ti alaini-baba: ṣe otitọ si awọn olupọnju ati alaini. Gba talaka ati alaini: yọ wọn ni ọwọ awọn eniyan buburu. Nwọn ko mọ, bẹẹni wọn ko fẹ ki oye ki o ye wọn: nwọn nrin ni okunkun; gbogbo ipilẹ aye yẹ ni ipo wọn. Emi ti wipe, ọlọrun ni eyin; awọn ọmọ Ọga-ogo si ni gbogbo yin. Ṣugbọn ẹyin o ku bi eniyan, eyin o si ṣubu bi ọkan ninu awọn ọmọ-alade. Ọlọrun, dide, ṣe idajọ aye: nitori iwọ ni yoo ni orile-ede gbogbo.
Posted on: Sat, 28 Sep 2013 08:56:29 +0000

Recently Viewed Topics




© 2015